Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti orileede Naijiria ti sọrọ idanloju wi pe iṣakoso oun ti ṣẹgun iṣoro to n koju eto aabo kaakiri orileede Naijiria.
Tinubu lo sọ eyi lasiko to n b’awọn ọmọ Naijiria sọrọ lalẹ ọjọ Aje to kọja yii nileeṣẹ tẹlifiṣan NTA.
Aarẹ sọ pe asiko ti a wa yii, awọn ọmọ Naijiria le rin irin ajo lopopona lai si ibẹru mọ, leyi to ni iru rẹ ti ṣẹlẹ tipẹ.
O ni gbogbo ohun to n ba awọn araalu lẹru, to si n gbe ọkan wọn soke bi wọn ba fẹẹ rin irin ajo ọna jinjin lawọn ti yanju patapata.
“Lonii, mo ni igboya ninu alakalẹ eto aabo orileede yii. Ẹ ṣi le maa rin irin ajo ori ilẹ. Ṣaaju asiko yii, ko ṣee ṣe. Iṣẹ kan ṣoṣo lo gba lati dabaru eto agbegbe kan, ṣugbọn sibẹ, a ko le maa fọwọ yẹpẹrẹ mu igbiyanju awọn ologun nitori oniruuru ikọli bi eyi to ṣẹlẹ ni Brigade Battalion,” Aarẹ lo sọ bẹẹ.
Bakan naa lo rọ awọn ọmọ Naijiria lati maa wa ni ikiyesara, nitori pe awọn awoye nile ati lẹyin odi ni wọn n wo aṣeyọri ilẹ yii.
“Ẹ ni lati gbaradi ni ida ọgọrun, wakati mẹrinlelogun lojumọ, lati rii daju pe awọn araalu wa labẹ aabo.”
No comments:
Post a Comment