A gbọdọ ri aridaju ohun to ṣokunfa iku Jimoh to ku sahamọ ọlọpaa – Gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 24, 2024

A gbọdọ ri aridaju ohun to ṣokunfa iku Jimoh to ku sahamọ ọlọpaa – Gomina AbdulRazaq


Gomina Abdulrahman Abdulrazaq tipinlẹ Kwara ti sọ pe iṣakoso oun ti bẹrẹ sii wo bi iṣẹ iwadii ṣe n lọ lati mọ iru iku to pa Jimoh Abdulqadir si ahamọ ọlọpaa nipinlẹ naa.

AbdulRazaq lo sọrọ naa lasiko abẹwo ti ọga ọlọpaa Naijiria, Kayode Egbetokun ṣe si ile mọlẹbi oloogbe naa.

Gomina sọ pe ilu ọkunrin naa ya wọn lẹnu, leyi to jẹ ko ba wọn lọkanjẹ pupọ.

“Iku Ọgbẹni Jimoh Abdulqadir ya wa lẹnu pupọ. O jẹ eyi to bani lọkanjẹ pupọ fun agbegbe wa. A ko le gba a,’Gomina sọ bẹẹ.

“Nigba ti a n ba Balogun Fulani, Alaaji Abubakar Sidiq Atiku Fulani ati awọn mọlẹbi oloogbe naa kẹdun, a n fẹ ki awọn alakoso agba nileeṣẹ ọlọpaa wadii ohun to ṣokunfa iku ọkunrin naa, ki wọn si rii daju pe idajọ ododo waye.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI