“Sugar Factory Film Studio” kọja gbọngan ayẹyẹ lasan - Gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 25, 2024

“Sugar Factory Film Studio” kọja gbọngan ayẹyẹ lasan - Gomina AbdulRazaq


Itan nla tuntun ni ipinlẹ Kwara tun fi balẹ lọjọ Aiku, Sande to kọja yii nigba ti ipinlẹ naa gbalejo awọn eekan-eekan lawujọ, paapaa lagboole tiata.

Eto ayẹyẹ alaragbayida to kọja afẹnuroyin lo waye ni gbọngan tuntun ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣẹṣẹ ṣagbekalẹ rẹ lati fi mu itẹsiwaju ba ipinlẹ naa, paapaa lẹka eto ọrọ aje ati igbanisiṣẹ.

Nibi akanṣe eto naa ti yoo kọkọ waye ninu gbọngan 'Sugar Factory Film Studio' naa ni gbegede ti gbina, nipa ariya ti ko wọpọ.

Awọn agbaagba ati gbajugbaja oṣere to fi mọ awọn alẹnulọrọ lagboole amuludun ni Naijiria ni peju sibẹ.

Awomaleelọ ni gbọngan naa jẹ fun ọpọ awọn eeyan to wa nibẹ, ti wọn si n gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRazaq lori agbekalẹ ọhun.

Akanṣe eto aami ẹyẹ ti wọn pe ni Best of Nollywood (BON), ẹlẹẹkẹrindinlogun iru rẹ lo waye lọjọ Aiku, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2024.

Nibẹ ni wọn ti fi aami ẹyẹ da awọn ogbontarigi oṣere tiata ti wọn ti fakọyọ daadaa lọla, koda ti awọn akopa tun n gbe oṣuba kare fawọn alakoso eto aami ẹyẹ ọhun lori bi wọn ṣe yan ipinlẹ Kwara laayo fún ayẹyẹ tọdun yii.

Bakan naa, ni eto ọhun tun fun gomina ni anfaani lati pokiki ipinlẹ Kwara lẹka eto ṣiṣe sinima, irin ajo afẹ ati igbanilalejo to yanranti, to fi mọ imọ ẹrọ ati erongba rere nipa iṣẹ ọwọ.

Gomina AbdulRazaq nigba to n sọrọ, jẹ ko du mimọ pe idunnu nla lo jẹ foun lati gba awọn oṣere lalejo, pẹlu akanṣe eto nla naa.

Ninu ọrọ rẹ, gomina ṣalaye pe nitori ifelẹ toun ni si idagbasoke ati eto amuludun, to fi mọ irin ajo afẹ lo jẹ koun ṣagbekalẹ gbọngan naa.

“Inu mi dun lati gba yin lalejo si ipinlẹ Kwara, mo si dupẹ lọwọ yin fun bi ẹ ti ṣe bọwọ fun wa lati wa nibi. Eto tonii waye ni gbọngan Sugar Factory Film Studio, eyi a kọ lati ṣagbelarugẹ fun yiya sinima, gbigbe ẹbun ibilẹ dide, ati mimu ki Kwara wa ni ipele nla fuj gbigbe sinima jade.

“Sugar Factory Film Studio kọja gbọngan ayẹyẹ lasan; o ṣapejuwe bi iṣakoso wa ṣe farajin lati gbaruku ti idagbasoke ẹbun ọrọ aje."

Lara awọn agbaagba oṣere ati amuludun to wa nibẹ ni Fred Amata; Hilda Dokubo; Tunji Bamishigbin; Gloria Anozie; Ayo Magaji; Bimbo Manuel; Keppy Bassey Ekpeyoung; Yomi Fash-Lanso; Toyin Abraham; Lillian Aluko; atii Aisha Lawal.

Awọn miran ni Kanayo O. Kanayo, Femi Adebayo, Odunlade Adekola, Mercy Aigbe, Adebayo Tijani, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ko

















No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI