Ko si iroyin meji to n ja rainrain kaakiri Naijiria lasiko yii, to kọja bi gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ẹdo, Sẹnetọ Monday Okpebholo ṣe fẹsun kan gomina ipinlẹ naa, Godwin Obaseki wi pe o ti na papa bora.
Okpebholo lo ke gbajare ọhun sita ninu atẹjade ti Godspower Inegbe fi sita lọjọ Aiku, oni, nibi to ti bu ẹnu atẹ iwa to sọ pe Ọbasẹki hu.
Gomina tuntun naa sọ pe jẹ ko di mimọ pe ko sẹni to le sọ ibi ti Ọbasẹki wọle si lẹyin to na papa bora kuro niluu Benin, olu-ilu ipinlẹ Ẹdo.
Bọọsi kekere kan lo sọ pe Ọbasẹki lo lati salọ kuro nipinlẹ naa, pẹlu erongba lati gba ilẹ olominira Benin lati lọ soke okun.
O ni lọjọ Ẹti to kọja ni Ọbasẹki le gbogbo awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ, to fi mọ gbogbo eeyan to wa nile ijọba danu, to si ni ki onikaluku gba ile wọn lọ, lẹyin eyi lo ni ọkunrin naa juba ehoro nigba to ku wakati mejilelaadọrin ko gbe ipo silẹ.
No comments:
Post a Comment