Ọṣilẹ ni lati ni imọ ohun to wa ninu iwe ofin oye jíjẹ nipinlẹ Ogun yekeyeke - Olu Orile-Ikija ṣekilọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 3, 2024

Ọṣilẹ ni lati ni imọ ohun to wa ninu iwe ofin oye jíjẹ nipinlẹ Ogun yekeyeke - Olu Orile-Ikija ṣekilọ


Olu tiluu Orile-Ikija nipinlẹ Ogun, Ọba Babatunde Kọlawọle Ayọrinde ti rọ Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, Ọba Adedapọ Adewale Tẹjuoṣo lati ni imọ kikun nipa awọn ohun to wa ninu iwe ofin oye jijẹ nipinlẹ Ogun, eyi ti ijọba ṣagbeyẹwo rẹ lọdun 2021 ati 2024.

Ọba Ayọrinde sọ pe eyi yoo dẹkun wahala ati awuyewuye to n ṣẹlẹ nipa ofin to de awọn ọba alaye lori ibi ti wọn n ṣakoso le lori.

Kabiyesi naa lo parọwa yii lasiko to n ba AWIKONKO sọrọ laipẹ yii, nibi to ti jẹ ko di mimọ pe ofin oye jijẹ ti yipada si ti ọdun 1957 ti awọn kan ṣi n tọka si.

Ọba alaye naa sọ pe latigba ti ijọba ti ṣe agbeyẹwo, ti wọn si ti ṣe ayipada ninu iwe ofin oye jijẹ, ni aala ti wa lori ibudo ti awọn ọba yoo maa ṣakoso.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni Ọba Oluṣẹgun Alexander MacGregor fẹsun kan awọn oloye ilu Ilawọ wi pe wọn n huwa ibajẹ, ti wọn si n sa sabẹ Ọba Ọṣilẹ lati fi boju.

Ọba MacGregor sọ pe oun ko le laju silẹ, ki wọn ba ilu jẹ mọ ohun lori, idi pataki to fi rọ awọn oloye mẹwaa loye lati ori Oluwo, Balogun ati Jagunna.

Nigba to n sọrọ, Ọba Ayọrinde sọ pe "Ohun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ bayii, nko si fun ọtẹ rara. Nigba kan ri, ara Oke-Ọna ni Ikija ati Ilawọ wa. Ilugun, Idomapa ati awọn miran naa wa lara Oke-Ọna Ẹgba.

"Nigba atijọ ni gbogbo iyẹn ti ṣẹlẹ, ṣugbọn lọwọlọwọ bayii, wọn ti fun Ikija ni ọba, Olu Orile-Ikija si ni wọn pe e, o si wa ninu awọn oba ti iwe ofin oye jíjẹ da mọ, iyẹn iwe ofin oye jíjẹ nipinlẹ Ogun ti wọn ṣagbeyẹwo ati atunṣe rẹ lọdun 2021 ati 2024.

"Ipo Ọba pin si meji, ipo akọkọ ni awọn ọba ti wọn da mọ ninu iwe ofin (recognized chiefs), nibẹ si ni Olu Orile-Ikija wa pẹlu Olu Orile-Ilawọ.

"Eyi tunmọ si pe Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba ati Ọba Ikija, to fi mọ Ọba Ilawọ, ẹgbẹ kan naa ni wọn jẹ, nitori pe ipo kan naa ni wọn wa ninu iwe ofin oye jíjẹ.

"Apakeji ni awọn ọba ti wọn n pe ni ọba kereje (coronet oba) wa, iyẹn awọn oba ti wọn gba igbega kuro ni ipo Baalẹ. Ikija kii ṣe ọba kereje, bẹẹ ni Ilawọ kii ṣe ọba kereje.


"Wọn jẹ ọba lori ilu ati agbegbe ni. Orisun wa ni Ikija Orile. Emi Ọba Babatunde Kọlawọle Ayọrinde, emi ni Olu Orile-Ikija.

"Wọn n pe ọrọ kan ni alaṣẹ, iyẹn tunmọ si pe alaṣẹ lori agbegbe to jẹ ọba le lori. Nibikibi tí awọn ọmọ ilu naa ba wa, ọba wọn lo ni aṣẹ lori wọn, o lẹ jẹ ninu ijọba ibilẹ tabi nibo miran.

"Gbogbo ẹya Ikija to wa ni Ọdẹda, Ifọ, Agbado, Wasinmi ati gbogbo ibi ti ọmọ Ikija ba ti wa, ọba kan ṣoṣo ni alakoso wọn ni tile-toko."

Ọba Ayọrinde sọ pe bo ṣe ri Ikija naa lo ri ni Orile-Ilawọ, ati pe Ikija nibi ti Olumọ wa, Olu Orile-Ikija ni ọba wọn.

Kabiyesi ni imọ ni ko to fun awọn eeyan, nitori pe ede oyinbo ni wọn fi kọ iwe ofin oye jíjẹ, to si lo yẹ ko ye wọn yekeyeke.

"Mo maa fẹ lo asiko yii lati dupẹ lọwọ Ọba Alexandra Oluṣẹgun MacGregor, Olu Orile-Ilawọ fun bo ṣe jade sita lati tan imọle sawọn ohun to ṣokukun, ki awọn ti ko ni oye le mọ bo ṣe jẹ, paapaa julọ awọn oloye Oke-Ọna.

"Gbogbo wahala ti Ọba Ọṣilẹ n ba Ọba MacGregor fa, nitori kabiyesi jẹ eeyan tutu ni. Ẹya temi yatọ si ti Ọba MacGregor, mi o gba igbakugba.

"Ilu to da duro ni Orile-Ikija, ko si labẹ Ọṣilẹ Oke-Ọna. Awọn ọba bii Alake, Olowu Ọṣilẹ, Agura, Ikija, Ilawọ to fi mọ awọn miran ni wọn ni ileto ti wọn jọba le lori.

"Iwe ofin oye jijẹ ti agbeyẹwo ọdun 2021 ati 2024 ṣalaye finnifinni fun wa lai fi igba kan bo ọkan ninu.

"Ohun ti Ọba Ọṣilẹ gbọnju ba ni pe oun ni alakoso ilu bii mẹfa si mẹjọ, ṣugbọn bi igba ṣe n yi, lo n jẹ ki ofin naa maa yipada.

"Ki idagbasoke si le ba gbogbo agbegbe lo jẹ ki ofin maa yipada. Bii ilara ni mo ka a si. Ofin ọdun 1957 ni Baba Ọṣilẹ ṣi n tọka si lọdun 2024, nigba ti nnkan ti yipada tipẹ, ko yẹ ko ri bẹẹ.

"Oko ni Ọṣilẹ ti wa, awa si yato si Oko, fun idi eyi, a ko si labẹ iṣakoso Ọṣilẹ."

Ọba Ayọrinde wa rọ gbogbo awọn ti oye ko ye lati wa iwe ofin oye jíjẹ nipinlẹ Ogun, ko si ye wọn yekeyeke.

Kabiyesi naa ni, awọn araalu gbọdọ mọ ofin to de wọn nipa ọrọ oye jijẹ bi igba ṣe n yi, ti ijọba si n ṣe agbeyẹwo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI