Ọrọ ti wọn sọ pe Jesu Olugbala sọ gbẹyin lori igi agbelebu wi pe 'o pari' naa lo jade lẹnu ogbologbo afurasi ajinigbe kan tọwọ tẹ nipinlẹ Delta laipẹ yii.
Bi Jesu ati afurasi ajinigbe naa ṣe sọ 'o pari' lo yatọ sira wọn.
Niṣe la gbọ pe awọn ọlọpaa ṣe ofintoto gidi ko to di pe ọwọ palaba ọkunrin naa segi pelu awọn nnkan ija oloro loriṣiriṣi ti wọn ka mọ-ọn lọwọ.
Olumuyiwa Adejọbi to jẹ agbẹnusọ agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lo fi iroyin ọhun lede loju opo 'X' rẹ laipẹ yii.
No comments:
Post a Comment