Ọba MacGregor rọ oloye mẹwaa loye niluu Ilawọ lẹẹkan ṣoṣo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 1, 2024

Ọba MacGregor rọ oloye mẹwaa loye niluu Ilawọ lẹẹkan ṣoṣo


Olu tiluu Orile-Ilawọ nipinlẹ Ogun, Ọba Oluṣẹgun Alexander MacGregor ti rọ oloye ti ko din ni meje nipo lori ẹsun gbigbabọde fun ilu naa.

Ọba MacGregor sọ pe awọn eeyan naa ko yẹ lẹni ti wọn le maa pe ni oloye laarin ilu Ilawọ, nitori iwa adojutini ti wọn n hu lawujọ.

Kabiyesi naa to tun jẹ Ọjọgbọn lẹka imọ iṣegun oyinbo lo kede irọloye naa nibi ipade awọn akọroyin to waye ni aafin Orile-Ilawọ to wa niluu Abẹokuta.

Samson Oluwọle Dosunmu to jẹ Oluwo, Abraham Adebayọ Adisa Ṣoyọye to jẹ Balogun ati Fatai Ṣodimu to jẹ Jagunna ni awọn mẹtẹẹta ti Ọba MacGregor loun rọ loye.

Lara awọn ẹsun ti ọba alaye naa fi kan wọn ni pe wọn n ta ilẹ ilu lai bikita, igbimọ ọtẹ ati titapa si aṣẹ kabiyesi.

Ọba MacGregor sọ pe ilẹ to le ni ẹgbẹrun kan ataabọ (1,600 acres) ni awọn eeyan naa ti ta danu, to si ni ko si ninu iṣe ilu naa lati maa ta ilẹ, paapaa fun awọn ajoji.

"Awọn eeyan yii kii ṣe oloye mi, nitori pe ọba miran ni wọn n ṣatilẹyin, kii ṣe emi, ọdọ ọba naa si ni wọn ti n ṣe ipade wọn, kii ṣe ilu Ilawọ.

"Awọn wọnyi kii ṣe oloye niluu Ilawọ, Oke-Ọna ni wọn ti joye. Ipo Oluwo, Balogun ati Jagunna ti ṣofo bayii. Awọn to di ipo naa mu tẹlẹ ko ṣoju ilu, wọn ko si ṣoju emi ti mo jẹ ọba.

"Oloye Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba ni wọn. Mo si maa darukọ gbogbo wọn fun un yin.

"Ninu igbimọ afọbajẹ, a ni awọn Ologboni, Ologun ati Olorogun. Oluwo ni olori awọn Ologboni.

"Samson Oluwọle Dosunmu to n pe ara rẹ ni Oluwo kii ṣe Oluwo ilu Ilawọ mọ, Baala Oke-Ọna ni; Abraham Adebayọ Adisa Ṣoyọye to n pe ara rẹ ni Balogun kii ṣe Balogun ilu Ilawọ mọ, Baṣọrun Oke-Ọna ati Akọgun Ẹgba lo jẹ.

"Eyi to n pe ara rẹ ni Jagunna, Fatai Ṣodimu ko ri bẹẹ mọ. Awọn olori awọn oloye ree, ati pe wọn tun ṣi ni awọn oloye miran labẹ wọn ti wọn jọ n huwa buruku yii.

"Ẹnikan wa to n pe ara rẹ ni igbakeji Oluwo, Olufẹmi Adebayọ Adenaike lorukọ rẹ, o n tan ara rẹ jẹ ni, ko si ẹni to n jẹ Aro Ilawọ ninu iwe akọsilẹ mi. A tun ni ẹnikan to n pe ara rẹ ni Ogboye Ilawọ, Isaac Olubanji Ọlaogun lorukọ rẹ, ko si ninu iwe akọsilẹ mi rara.

"Ẹnikan naa tun wa to n pe ara rẹ ni Ẹkẹrin Ilawọ, Oluwọle Ayọrinde lorukọ tiẹ; eyi to n pe ara rẹ ni Bada Ilawọ, Joseph Abiọdun Ṣowunmi; to fi mọ eyi to n pe ara rẹ ni Mayegun Ilawọ, Rilwan Tajudeen Abudu.

"Bẹẹ naa la tun ni Ifayẹmi Adisa to n pe ara rẹ ni Baasẹmọ, ati Lawrence Ogunsanya to n pe ara rẹ ni Apagunpọtẹ, gbogbo awọn wọnyi ni mo fẹ ki gbogbo agbaye mọ pe wọn kii ṣe oloye niluu Ilawọ mọ.

"Abẹ Oke-Ọna ni wọn n sapamọ si lati ṣiṣẹ ibi wọn yii. Idi ti nko ṣe tete sọrọ sita ni pe mo farabalẹ ṣe iwadii kikun lori wọn, mo si mu wọn lọrun ọwọ, lẹyin ti aṣiri tu sita."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI