Olu tiluu Orile-Ikija, Ọba Babatunde Kọlawọle Ayọrinde ti sọ fun Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, Ọba Adedapọ Adewale Tẹjuoṣo lati dẹkun lilo awọn oloye ilu Ilawọ lodi si ọba wọn, Ọba Oluṣẹgun Alexander MacGregor.
Olu tiluu Orile-Ikija, ti wọn tun n pe ni Alakija lo sọ eyi di mimọ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ laipẹ yii ni Aafin rẹ to wa lagbegbe Iyana-Ilogbo, ipinlẹ Ogun.
Ọba alaye naa sọ pe iyalẹnu nla lo jẹ lati rii pe Ọba Tẹjuoṣo n ṣagbatẹru awọn oloye Oke-Ọna ti wọn n tako Ọba MacGregor, to si ni ko bojumu to.
Ẹkunrẹrẹ wa ninu fidio yii
No comments:
Post a Comment