O tan! Ijọba Kwara ti ileeṣẹ 'Harmony Transport' pa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 7, 2024

O tan! Ijọba Kwara ti ileeṣẹ 'Harmony Transport' pa


Lojuna lati mu ayipada rere ba eto igbokegbodo ọkọ ati irinna to ja geere, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti paṣẹ pe ki wọn ti ileeṣẹ Harmony Transport Services Limited ti ọpọ mọ si Kwara Express pa.

Gomina AbdulRazaq gbe aṣẹ yii kalẹ lati mu ayipada ọtun ba eto igbokegbodo ọkọ ati irinna to ja geere nipinlẹ naa, paapaa ilọsiwaju eto ọrọ aje.

Ninu atẹjade ti awọn alakoso ileeṣẹ Harmony Transport gbe jade l'Ọjọru, ọsẹ yii, wọn ni ijọba Kwara ṣe daadaa fun gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata.

Wọn ni gbogbo awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ni ijọba Kwara san owo to yẹ fun, gẹgẹ bi ajẹmọnu wọn lai yọ ẹnikẹni silẹ.


Awọn alakoso naa jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe ko rọrun lati san owo ajẹmọnu fawọn oṣiṣẹ ti wọn ni ki wọn maa lọ sile, sibẹ o ṣe pataki lati gbe igbesẹ akikanju naa.

Siwaju sii la gbọ pe oriṣiriṣi ọrọ ati esi ti ijọba ti gba nipa idi to fi ṣe pataki lati mu idagbasoke ba igbokegbodo ọkọ lo fa igbesẹ ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI