O ṣẹlẹ! Babalawo to yinbọn funra rẹ lati dan oogun ayẹta wo dero ile iwosan l’Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, November 30, 2024

O ṣẹlẹ! Babalawo to yinbọn funra rẹ lati dan oogun ayẹta wo dero ile iwosan l’Abuja


Ọrọ buruku toun tẹrin niluu Abuja nigba ti wọn sọ pe ọkunrin kan, Ismail Usman to yan iṣẹ babalawo laayo deedee yinbọn funra rẹ lati dan oogun ayẹta to ṣẹṣẹ ṣe wo, ṣugbọn ti ọrọ pada bẹyin yọ fun un.

Abule Kuchibuyi to wa niluu Federal Capital Territory, Abuja niṣẹlẹ ọhun ti waye lọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2024 ti a wa yii.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe ṣalaye, a gbọ pe niṣe ni Usman ṣẹṣẹ pese oogun abẹnugọngọ to n ṣiṣẹ fun ayẹta, lati le maa lo o loju ogun.

Lẹyin naa lo gbe ibọn, to si yin in fun ara rẹ nikun.

A gbọ pe niṣe lọrọ ọrọ ọhun bẹyin yọ, nigba ti wọn ni ibọn naa wọnu ikun rẹ lọ, to si ṣubu lulẹ pẹlu ọgbẹ ati irora nla.

Awọn ẹlẹyinju aanu ladugbo rẹ ti wọn gburo ibọn la gbọ pe wọn sare lọ lati wo ohun to ṣẹlẹ, to si jẹ iyalẹnu nigba ti wọn ba a lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, agbẹnusọ ọlọpaa niluu Abuja, Josephine Adeh jẹ ko di mimọ pe awọn ara agbegbe naa lo ranṣẹ ipe pajawiri si awọn.

O ni awọn ọlọpaa awọn ni ẹkun Byazhin Division lo sare lọ sibẹ lati gbe Usman digbadigba lọ si ọsibitu ijọba to wa ni Kubwa lati doola ẹmi rẹ.

Adeh fi kun ọrọ rẹ pe ọkunrin naa farapa gidigidi, idi ree ti wọn fi tare rẹ si ile iwosan Gwagwalada Specialist Hospital, nibi ti awọn dokita ti n ṣiṣẹ takuntakun lati doola ẹmi rẹ.

“Ọkunrin kan to n jẹ Shandam Michael lo ranṣẹ ipe pajawiri nipa Ismail Usman, babalawo kan to yinbọn funra rẹ lasiko to n gbiynaju lati dan agbara oogun abẹnugọngọ rẹ wo, eyi to pe ni ayẹta ibilẹ. Ikun ni Usman ti yinbọn funra rẹ.

“O ṣeni laanu wi pe oogun abẹnugọngọ naa dalẹ Usman, to si mu ko wa ni baaku-baala pẹlu ifarapa nla. Awọn ọlọpaa wa lati ẹkun Byazhin ni wọn sare lọ doola ẹmi rẹ.”

Bakan naa lo sọ pe awọn ti yẹ ile rẹ wo, wọn si ti ṣawari ibọn agbelẹrọ to n lo, ati pe bo tilẹ jẹ pe Usman n gba itọju lọwọ, sibẹ o ti tapa si ofin lilo ibọn ati igbiyanju lati gba ẹmi ara ẹni ti abala 231 ninu iwe ofin ẹkun Ariwa.

Bẹẹ lo ni Kọmiṣanna ọlọpaa FCT, Ọlatunji Disu bu ẹnu atẹ lu iwa naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI