Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Olomore si Brewery to wa niluu Abẹokuta nirọlẹ ọjọ Ẹti to kọja yii, nigba ti wọn sọ pe awọn agbebọn yinbọn pa ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Mutiu Akinbami.
Ori ọkada ni wọn sọ pe Akinbami wa pẹlu ọmọ rẹ obinrin lasiko ti wọn yinbọn pa a danu sẹgbẹ opopona.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni Akinbami, ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ọnarebu Igor lo jẹ ọkan lara awọn Kansẹlọ to gbe ipo silẹ laipẹ yii nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta.
Ipo alaabọ ara ti Ọnarebu Igor wa lo jẹ ko tun gbajumọ daadaa, to si tun n fi ẹsẹ naa gun ọkada funra rẹ kaakiri.
AWIKONKO gbọ pe nnkan bi aago mẹfa kọja iṣẹju mẹtala irọlẹ ni wọn yinbọn pa Igor.
Inu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Hilux ti ko ni nọmba idanimọ ni awọn to yinbọn pa ọkunrin ọhun wa lasiko naa.
Aarin meji agbegbe Olomore si Brewery ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Irin la gbọ pe Igor fi n rin lẹyin ti wọn ge ẹsẹ rẹ danu
Lara awọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn sọ pe ile ni wọn ti n tẹle Igor, iyẹn ninu Olomoore Federal Housing Estate (FHE), ko to di pe wọn dena de e mọlẹ nibi ti wọn pa a si.
Díẹ lara awọn to mọ Igor nibi iṣẹlẹ naa ni wọn n sọ pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ni, nigba aye rẹ, bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ.
Ṣugbọn ṣa o, gbogbo akitiyan lati ba agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla sọrọ lori iṣẹlẹ naa lo ja si pabo titi digba ti a pari akojọpọ iroyin yii.
No comments:
Post a Comment