Nko mọ ohunkohun nipa awọn to ra ibo lorukọ mi - Aiyedatiwa pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 18, 2024

Nko mọ ohunkohun nipa awọn to ra ibo lorukọ mi - Aiyedatiwa pariwo sita


Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa ti wọn tun ṣẹṣẹ dibo yan ti pariwo sita wi pe oun ko mọ ohunkohun nipa awọn ti wọn loo ra ibo lorukọ oun, nitori pe oun ko lọwọ si iwa naa.
 
Aiyedatiwa lo sọrọ naa lalẹ ọjọ Aiku, Sannde to kọja, lasiko to n farahan lori eto to waye nileeṣẹ amohunmaworan Channels.
 
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni oriṣiriṣi ẹsun jade sita wi pe awọn gomina ra ibo lawọn ibudo eto idibo kaakiri ipinlẹ naa.
 
Gbogbo ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo ni Aiyedatiwa ti jawe olubori, lati fẹyin awọn alatako rẹ gbọlẹ kọja sisọ.
 
Aiyedatiwa ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe awọn alatako oun ni wọn  n fi ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ kan oun, nitori bi wọn ṣe padanu.
 
“Nko mọ ohunkohun nipa ẹsun naa. Awọn alatako mi yoo fẹẹ maa wa awawi lati fẹsun kan mi lori bi wọn ṣe padanu, ṣugbọn fun awa, ohun ti a ṣiṣẹ fun ni; awọn eeyan si ti sọrọ pẹlu ibo wọn.
 
“Ko le si idi kankan ni pato lati ibo  nitori pe awọn araalu mọ ohun ti wọn n fẹ. Nko mọ ohunkohun nipa wi pe awọn eeyan n fi orukọ mi ra ibo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI