Nitori mo kọ lati ra ibo lo jẹ ki n padanu - Oludije gomina lẹgbẹ oṣelu ADC l'Ondo sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 18, 2024

Nitori mo kọ lati ra ibo lo jẹ ki n padanu - Oludije gomina lẹgbẹ oṣelu ADC l'Ondo sọrọ


Oludije sipo gomina ipinlẹ Ondo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, Myson Nejo ti tu awọn aṣiri nipa idi to ti ba ijakue pade nibi eto idibo to waye lopin ọsẹ to kọja.

Nejo sọ pe ohun to waye nipinlẹ naa lọjọ Abamẹta to kọja kii ṣe eto idibo bi ko ṣe pe okoowo ibo lasan ni.

Ọkunrin naa to ṣe ipo kẹta ninu eto idibo ọhun pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹrin le diẹ (4,138) jẹ ko di mimọ pe awọn to le fi owo ra ibo ni wọn jawe olubori.
oun ko le lọwọ si rira ibo.

O ni bo tilẹ jẹ pe oun padanu, sibẹ ọkan oun balẹ daadaa.

“Mo dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo wi pe wọn dibo fun mi. Lai fun wọn lowo, wọn tun ṣi dibo fun mi. Mo fẹẹ nigbagbọ pe ibo mi fẹsẹ mulẹ nitori ko sohun to n jẹ pe wọn ra ibo tabi iwa ti ko ba ofin mu.

"Ju gbogbo rẹ lọ, mo fẹẹ nigbagbọ pe emi ni ml bori ninu eto idibo yii,” o jẹ ko di mimọ.

Nipa ti ibo to ni wọn n ra, Nejo sọ pe awọn eeyan n ta ibo ni ẹgbẹrun lọna ogun naira, to si ni itiju nla lo jẹ.

“Awọn eeyan n ra ibo ni ẹgbẹrun lọna ogun naira tabi ẹgbẹrun mẹẹdogun naira, ati pe ni ibudo idibo mi, laarin ẹgbẹrun mẹwaa si mẹẹdogun naira ni wọn n ra ibo nibẹ.

“Nitori nko lowo lọwọ, ti mo si sọ fun wọn pe mi o ni fun wọn lowo lati ra ibo, ibo meji pere ni mo pada ni ninu ogoji ibo ti wọn di ni ibudo idibo mi.

“Ṣugbọn ko jọ mi loju. Awọn eeyan n pe mi, wọn n beere owo lọwọ mi lati ra ibo, ṣugbọn mo duro lori ipinnu mi. Bi wọn ba fẹẹ dibo, ki wọn lọ dibo, nko nii fun wọn lowo lati ra ibo.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI