Ariwo ayọ nla lo sọ lagboole awọn ololufẹ gbajugbaja ọga ẹgbẹ onimọto nipinlẹ Eko tẹlẹ nni, Musiliu Akinsanya nigba ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi alaga apapọ fẹgbẹ awakọ NURTW kaakiri Naijiria.
Akinsanya ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si MC Oluọmọ ni awọn alakoso ẹgbẹ naa kede rẹ gẹgẹ bi alaga apapọ, lẹyin eto idibo to waye laipẹ yii.
Ẹgbẹ awọn awakọ ero ni Naijiria, NURTW, ti dibo yan Musiliu Akinsanya, ti ọpọ mọ si MC Oluomo gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ naa ni Naijiria.
Ọjọ Abamẹta to kọja yii la gbọ pe eto idibo lati yan alaga apapọ tuntun fẹgbẹ naa waye nipinlẹ Eko, ti a si gbọ pe oun nikan naa ni oludije sipo ọhun.
AWIKONKO gbọ pe ko sẹni to ba MC Oluọmọ dije du ipo ọhun, leyi to jẹ ko wọle wọọrọwọ lai daamu jinna.
Gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ awakọ kaakiri ilẹ Yoruba bii ipinlẹ Eko, Ogun, Ondo ati Ekiti ni wọn kopa ninu eto idibo ọhun.
Asiko ti wọn n ṣe ipade ẹgbẹ naa to maa n waye lẹẹkan laarin ọdun meorin ni eto idibo naa waye, ti Aarẹ fidihẹ ẹgbẹ ọhun, Aliyu Issa-Ore, si boju to o.
Nigba to n sọrọ, Issa-Ore sọ pe gẹgẹ bii ofin ẹgbẹ naa ṣe sọ, awọn eeyan ẹkun ti ipo a”laga ba kan lo maa dibo ti wọn yoo si fa ẹni ti wọn ba dibo yan le gbogbo ẹgbẹ naa lọwọ lati maa dari wọn.
O ni “Awọn ọmọ ẹgbẹ wa ni ekun iwọ oorun ti ṣe ohun to tọ gẹgẹ bii alakala ofin ẹgbẹ wa.”
Nibi eto idibo naa ni wọn tun ti yan Tajudeen Agbede, gẹgẹ bii igbakeji Aarẹ ni ẹkun iwọ oorun.
Ni kete ti wọn burawọle fun tan ni MC Oluomo, ti awọn ololufẹ rẹ rọgba yika sọ fun awọn eeyan naa ki wọn ṣiṣẹ papọ, ki wọn si gba alaafia laaye ninu ẹgbẹ ọhun.
O ni “Mo ti dariji gbogbo awọn to ṣẹ mi, mo si ke si gbogbo awọn ti mo ti ṣẹ ki awọn naa dariji mi.”
Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu, fun atilẹyin rẹ, o tun dupẹ lọwọ awọn gomina ipinlẹ Eko, Ondo ati Ekiti fun ifọwọsowọpọ wọn pẹlu.
No comments:
Post a Comment