Ileeṣẹ Adron Homes yan awọn alakoso tuntun fun ayipada rere - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 17, 2024

Ileeṣẹ Adron Homes yan awọn alakoso tuntun fun ayipada rere


Ileeṣẹ Adron Homes to n ta ile, ilẹ ati dukia kaakiri orileede Naijiria ati agbegbe rẹ ti yan awọn alakoso tuntun ti yoo maa tukọ iṣakoso ileeṣẹ naa fun ilọsiwaju ati idagbasoke alailẹgbẹ.
 
Eyii ni lati tubọ maa tẹ gbogbo awọn onibara lọrun ni gbogbo ọna, ati lati wa iyanju si awọn kudiẹkudiẹ to ṣeeṣe ko jẹyọ.

Awọn alakoso tuntun yii la gbọ pe wọn ti ṣiṣẹ takuntakun, ti wọn si ti ko ipa to pọ ninu idagbasoke ileeṣẹ ọhun.
 
Akọṣẹmọṣẹ ti ipa rere wọn ko ṣee gbagbe ni awọn alakoso tuntun ọhun, ti wọn si ti gbe ileeṣẹ naa larugẹ kọja afẹnuroyin.
 
Lara awọn alakoso tuntun naa ni Adenikẹ Ajọbọ toun jẹ alakoso ati oludari; Olubunmi Akinfẹ toun jẹ igbakeji alakoso; Ihuoma Azuru toun jẹ amugbalẹgbẹ alakoso fun eto tita ati ipolowo nipinlẹ Eko; Barbie Ette toun jẹ amugbalẹgbẹ alakoso fun eto tita ati ipolowo lẹkun Ariwa Naijiria.
 
Awọn yooku ni Ọdunọla Ogundapọ toun jẹ amugbalẹgbẹ alakoso fun eto tita ati ipolowo nilẹ Naijiria; Ọlasumbọ Oguntoye toun jẹ alakoso agba lẹka ile gbigbe ni Naijiria, ati Haastrup toun jẹ alakoso agba lẹka eto ikansira-ẹni fawọn onibara.
 
Gbogbo wọn ni yoo ṣiṣẹ papọ lati tubọ tẹsiwaju ninu eto idagbasoke ati ilọsiwaju ileeṣẹ Adron Homes.

Nigba to n sọrọ, Aarẹ Adetọla Emmanuel King gba wọn niyanju lati tubọ tẹpa mọ iṣẹ wọn fun ilọsiwaju to lọọrin.

Bẹẹ lo ni ki wọn farajin fun iṣẹ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI