Ijọba Kwara ti opopona Ile Apa pa, wọn pese ọna miran fawọn awakọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, November 23, 2024

Ijọba Kwara ti opopona Ile Apa pa, wọn pese ọna miran fawọn awakọ


Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede titi opopona Ile Apa to lọ si ikorira Tanke ati afara Tunde Idiagbon pa, bẹrẹ lati ọjọ Ẹti, Furaide to kọja.

Igbesẹ yii lo waye lati ṣe atunṣe agbegbe naa, lojuna lati mu idagbasoke ba igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Kwara.

Bi ẹ kko ba gbagbe, atunṣe ti n lọ lọwọ lopopona naa tẹlẹ, ṣugbọn to ku ki wọn da ọda 'Asphalt'' lee lori.

Ki iṣẹ to ja geere si le lọ bo ṣe yẹ, ni ijọba fi sọ pe o pọn dandan lati ti opopona ọhun pa.

Kọmiṣanna feto iṣẹ ode ati igbokegbodo ọkọ, Onimọ-ẹrọ Abdulquawiy Olododo jẹ ko di mimọ pe sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ yoo ṣẹlẹ lagbegbe naa, ṣugbọn awọn ti pese ọna miran fawọn awakọ lati gba de ibi ti wọn n lọ.

Onimọ-ẹrọ Olododo gba awọn awakọ lamọran lati ṣe jẹjẹ, ki wọn si ni suuru funra wọn ati pe ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu awọn oṣiṣẹ to n dari ọkọ lati jẹ ki lilọ ati bibọ ja geere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI