Ijọba ipinlẹ Kwara ti bu ẹnu atẹ lu bi olukọ kan nile ẹkọ girama tijọba, iyẹn Government Day Secondary School to wa lagbegbe Kukende niluu Ilọrin ṣe lu agunbanirọ lalubami, to si tun ja a sihoho.
Arabinrin Amuzat Fatima Nikẹ ni wọn pe orukọ olukọ naa to lu agunbanirọ toun naa n sin ilẹ Naijiria nike ẹkọ ọhun nilukulu
Kọmiṣanna feto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan nipinlẹ Kwara, Hajia Sa'adatu Modibbo Kawu lo bu ẹnu atẹ lu iwa naa, to si ni ẹlẹṣẹ ki yoo lọ lai jiya.
Hajia Modibbo Kawu nigba to n sọrọ lonii ọjọ Ẹti jẹ ko di mimọ pe awọn ko le tẹwọ gba iwa naa laarin ilu, paapaa ipinlẹ Kwara lapapọ.
O ni ijọba ko le gboju fo awọn iwa to le tabuku ba ipinlẹ naa nipa didabaru eto alaafia ati ife ẹ to ti wa nilẹ.
Igbimọ ijọba ti wọn pe ni Anti-Loitering Team nileeṣẹ naa, ati igbimọ iṣakoso ni Kwara State Teaching Service Commission ti wa ṣe abewo si ile ẹkọ lati ṣe iwadii ohun to ṣẹlẹ.
Nibẹ ni Kọmiṣanna ti rawọ ẹbẹ si ajo to n mojuto awọn agunbanirọ lati ma ṣe bunu lori ohun to ṣẹlẹ.
Bẹẹ ni wọn ṣeleri pe ijiya to tọ yoo waye fun olukọ naa, nitori pe awọn ti ranṣẹ pe e lati fọrọ wa lẹnu wo.
No comments:
Post a Comment