Ijọba Kwara ṣetan lati fun ẹgbẹẹgbẹrun akẹkọọ ni oogun aran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, November 23, 2024

Ijọba Kwara ṣetan lati fun ẹgbẹẹgbẹrun akẹkọọ ni oogun aran


Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe ohun ti ṣetan lati fun akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ to le ni idaji miliọnu (776,896) ni oogun aran ti wọn pe ni De-Worm.

Lati ọmọ ọdun marun si mẹrinla ni awọn ọmọ ti ijọba fẹẹ fun ni oogun naa kaakiri ijọba ibilẹ mẹẹdogun to wa nipinlẹ naa.

Igbese naa ni lati gbogun ti awọn aisan ati arun ti wọn pe ni Schistosomiasis and Soil-Transmitted Helminthiasis nipa lilo oogun rẹpẹtẹ ti wọn pe ni Mass Administration of Medicines (MAM) kaakiri ijọba ibilẹ mẹẹdogun.

Kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Kwara, Dokita Amina Ahmed El-Imam ti alakoso eto Neglected Tropical Disease (NTD), Arabinrin Yẹmisi Bamgboye ṣoju fun lo sọrọ nibi akanṣe idanilẹkọọ ọlọjọ mẹta to waye niluu Ilọrin.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni idanilẹkọọ ọhun ni lati ro awọn akopa lagbara nipa imọ ti wọn nilo lati le jẹ ki eto iponlongo oogun aran nipinlẹ ọhun lọ bo ṣe yẹ 

Dokita El-Imam jẹ ko di mimọ pe awọn niilo lati gbe eto ilera ati alaafia awọn ọmọde larugẹ, ki wọn si pe awọn obi ati alagbatọ, to fi mọ awọn alaṣẹ ile-ẹkọ lati gbaruku ti eto naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI