Ijọba Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kede Ọgbẹni Yusuf Bolaji La-Kadri gẹgẹ ọga agba ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ipawowọle nipinlẹ naa, KW-IRS.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, iyansipo naa bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lọjọ Aje, ọjọ kọkanla, oṣu kọkanla, ọdun 2024.
Akọṣẹmọṣẹ ni Bọlaji La-Kadri ninu eto iṣuna, iṣiro, to si ti ṣiṣẹ l'awọn ileeṣẹ nlanla bii Dangote Sugar Refinery Plc, Vodacom Business Africa, ati Price Waterhouse Coopers.
Bolaji La-Kadri ni imọ ẹkọ Bachelor of Science ninu imọ iṣiro ni fasiti ilu Ilọrin, bẹẹ lo tun jẹ ọmọ ẹgbẹ bii Chartered Institute of Taxation of Nigeria, (CITN); Chartered Accountants of Nigeria, (ICAN), Associate Chartered Management Accountant, (ACMA), ati Chartered Global Management Accountant, (CGMA), United Kingdom.
Bakan naa lo tun jẹ ọmọ ẹgbẹ Institute of Credit Administration, Nigeria, (MICA); Association of Corporate Treasurers of Nigeria, (ACTN); Society for Corporate Governance, Nigeria, (SCGN), ati Institute of Chartered Secretaries and Administrators of Nigeria (ICSAN).
No comments:
Post a Comment