Ijọba Kwara dide iranlọwọ nla fawọn to kagbako ijamba ori omi ni Gbajigbo lọjọsi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 24, 2024

Ijọba Kwara dide iranlọwọ nla fawọn to kagbako ijamba ori omi ni Gbajigbo lọjọsi


Ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Kwara, ti pin awọn ohun iranwọ to jọju fun awọn to fara kaasa ninu ijamba ori omi ni Gbajigbo, ijọba ibilẹ Kaiama lọjọsi.

Eyi lo waye pẹlu aṣẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq gbe kalẹ lati jẹ ki awọn araalu jẹ mudunmudun eto iṣejọba alagbada.

Lara awọn ohun iranwọ naa ni ounjẹ jijẹ bii Irẹsi, Agbado, Spaghetti, Ororo isebẹ, eelo isebẹ, to fi mọ awọn nnkan bii aṣọ awọn ọkunrin, obinrin ati tawọn ọmọde, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Akọwe agba ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ naa, iyẹn KWASEMA, Malaamu Saadu Mogaji ba awọn to fara kaasa ati awọn mọlẹbi wọn kẹdun, to si tẹnumọ idi to fi ṣe pataki lati maa mu ọrọ aabo ara ẹni lọkunkundun nigba ti wọn ba wa ninu ọkọ oju omi, nipa wiwa aṣọ aabo, ki wọn si dẹkun gbigbe ero rẹpẹtẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI