Ijọba ipinlẹ Kwara lohun ti bẹrẹ eto iforukọsilẹ fun gbogbo awọn akẹkọọ to n gbe nipinlẹ naa.
Abẹ eto ti wọn pe ni Kwara State Residents Registration Agency ni wọn ti fẹẹ ṣe eyo iforukọsilẹ ọhun fun gbogbo akẹkọọ ile ẹkọ giga kaakiri ipinlẹ naa.
Alaga fun ajọ KWSRRA, Ọgbẹni Tajudeen Jimoh lo fi iroyin naa lede lori amohunmaworan ipinlẹ Kwara laipẹ yii.
Jimoh ni awọn ti ṣe oju opo ayelujara kan, nibi ti gbogbo akẹkọọ yoo ti forukọsilẹ, nibi ti wọn yoo maa wọ lati ṣe iforukọsilẹ.
O ni lẹyin iforukọsilẹ naa, awọn akẹkọọ yoo ṣe abẹwo sile ileeṣẹ wọn lati tẹka ati yiya aworan wọn.
Bakan naa lo tun sọ pe o pọn dandan fun awọn oṣiṣẹ ijọba lati ṣe iforukọsilẹ, ati pe lai ṣe bẹẹ, wọn ko nii gba owo oṣu kọkanla.
O ṣalaye pe ipele mẹta ni eto iforukọsilẹ awọn oṣiṣẹ Kwara ijọba pin si, awọn ti wọn ko tii forukọsilẹ nitori iṣoro nọmba idanimọ, awọn to ti forukọsilẹ ṣugbọn ti wọn ko tii gb nọmba nitori awọn ipenija.
Ipele kẹta ni awọn ti wọn kọ lati tete forukọsilẹ, nitori ti wọn ro pe ko wulo.
No comments:
Post a Comment