Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti paṣẹ pe ki atunkọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ tijọba ibilẹ Adeta, iyẹn 'Adeta B LGEA Primary School', ijọba ipinlẹ Kwara bẹrẹ lakọtun.
Ọna igbalode ti yoo maa figagbaga pẹlu awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ lagbaye ni ijọba Kwara fẹẹ kọ ile ẹkọ ọhun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Ọpọ yara ikẹkọọ ati yara ikawe, to fi mọ ọfiisi awọn olukọ ati ọga ile-ẹkọ naa lo ti dẹnukọlẹ, pupọ rẹ ti wo lulẹ.
Eyi lo mu ki ijọba pinnu lati ṣe awopalẹ gbogbo ile ẹkọ naa, lati tun un kọ si ti igbalode mu.
Labẹ iṣakoso Gomina AbdulRazaq, eto ẹkọ n leke pẹlu bi ijọba ṣe mu-un lọkunkundun, nipa kiko owo lee lori fun idagbasoke to lọọrin.
No comments:
Post a Comment