Idunnu ṣubu lu ayọ! AbdulRazaq fa kọkọrọ bọọsi bọginni meji le ẹgbẹ akẹkọọ NANS, NAKSS lọwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 10, 2024

Idunnu ṣubu lu ayọ! AbdulRazaq fa kọkọrọ bọọsi bọginni meji le ẹgbẹ akẹkọọ NANS, NAKSS lọwọ


Orin ọpẹ ni ẹgbẹ awọn akẹkọọ ti National Association of Nigerian Students (NANS), ẹka tipinlẹ Kwara ati Association of Kwara State Students (NAKSS) lọwọ, fun irin ajo onirọrun.

Eyii ni lati mu inu awọn akẹkọọ iìnlẹ naa dun, lati le jẹ ki wọn mọ pe gomina fi wọn sọkan lati mu idẹrun ba iṣoro wọn.

Awọn aṣoju ẹgbẹ akẹkọọ mejeeji, Kọmureedi Issa Abdulgafar Arikewuyo ti NANS, ati Kọmureedi Abdulwahab Ridwan ti NAKSS dupẹ gidigidi lọwọ gomina fun ẹbun nla manigbagbe naa.
 
Nibẹ ni wọn ti ṣeleri wi pe awọn yoo tubọ maa ṣagbatẹru gomina ni gbogbo ọna, pẹlu bo ṣe nifẹẹ akẹkọọ, to si n wa gbogbo ọna lati ṣe ohun ti yoo mu idẹrun ba wọn ni gbogbo igba.






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI