Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti lọ si orileede France lati mu ki ajọṣepọ to dan mọnran wa laarin orileede naa ati Naijiria.
Ṣugbọn sibẹ, kii ṣe Aarẹ Tinubu nikan lo da lọ, oun pẹlu ikọ akọwọrin rẹ, leyi ti alaga ẹgbẹ awọn gomina Naijiria, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara wa lara wọn.
Yatọ si Gomina AbdulRazaq, iyawo aarẹ, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu ati awọn alẹnulọrọ ni Naijiria naa wa lara wọn.
Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ gomina lori eto iroyin igbalode, Ọlayinka Fafoluyi gbe jade, oni lati le jẹ ki ajọṣepọ to dan mọnran tubọ le wa laarin Naijiria ati France ni gomina ṣe tẹle aarẹ lọ.
Ipade ti yoo waye fọjọ mẹta naa yoo mu ibaṣepọ to dan mnọnran waye nipa eto iṣẹ agbẹ ati ọgbin, eto aabo, eto ẹkọ, eto ilera, ọrọ awọn ọdọ, imọ ẹrọ ati agbara ina mọnamọna .
Fafoluyi sọ pe bi Gomina AbdulRazaq ṣe wa nibi ipade naa, yoo jẹ ki ajọṣepọ naa tubọ gbookan sii nipa eto ọrọ aje, aṣa ati ibaṣepọ oṣelu to ti n waye tẹlẹ laarin ipinlẹ Kwara ati ijọba Faranse.
Lọdun 2023 to kọja ni ipinlẹ Kwara gba awọn alẹnulọrọ ilẹ Faranse lalejo, abẹwo ọhun ni minisita feto idagbasoke ipinlẹ ati baṣepọ awọn agbaye, Ọmọwe Chrysoula Zacharopoulou lewaju rẹ wọ ilu Ilọrin.
Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti tọwọ bọwe adehun meji pataki pẹlu ijọba Faranse naa nipa agbekalẹ eto imọ ẹrọ ti a mọ si Ilorin Innovation Hub.
Lọdun meji sẹyin ni aṣoju ilẹ Faranse si Naijiria lẹka eto aṣa, (Cooperation & Cultural Affairs), Ms. Emmanuelle Harang, lẹyin abẹwo to ṣe si gbagede naa, o gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRazaq lori igbesẹ naa.
No comments:
Post a Comment