Gomina AbdulRahman Abdulrazaq ti ipinlẹ Kwara ti buwọ lu afikun lori owo oṣu awọn oṣiṣẹ lati mu idẹrun ba wọn lori ipenija to n dojukọ eto ọrọ aje.
AbdulRazaq jẹ ko di mimọ pe afikun naa jẹ eyi ti yoo ṣanfaani fawọn oṣiṣẹ pẹlu ọwọngogo to wa nita, ti yoo si mu irọran ba igbokegbodo ọkọ lọ si ibiṣẹ.
Awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ ati ibilẹ kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara ni yoo maa gba afikun lori owo oṣu naa.
Oṣu mẹta gbako ni awọn oṣiṣẹ yoo fi gba owo yii gẹgẹ bi atẹjade ti ileeṣẹ eto iṣuna ipinlẹ Kwara gbe jade, eyi ti Kọmiṣanna, Ọmọwe Hauwa Nuru buwọ lu.
No comments:
Post a Comment