Gomina AbdulRazaq kẹdun iku Lagbaja, Hajia Aminat Dupẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 6, 2024

Gomina AbdulRazaq kẹdun iku Lagbaja, Hajia Aminat Dupẹ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti kẹdun iku ọgagun Taoreed Lagbaja to jẹ olori ikọ ọmọ ogun Naijiria, ẹni to dagbere faye lalẹ ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii 

Lagbaja ni iroyin fi to wa leti pe o tẹri gbaṣọ niluu Eko, lẹyin aisan rampẹ to kọluu.

Ninu atẹjade ibanikẹdun to fi ranṣẹ si Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu, alaga igbimọ ẹgb ẹ gomina ni Naijiria ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi akikanju ati olufọkansin nigba aye rẹ.

AbdulRazaq rọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ologun, mọlẹbi oloogbe lati mu ọkan le, pẹlu adura pe ki Ọlọrun tu wọn tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

Ninu iroyin miran to fara pẹ ẹ, Gomina AbdulRazaq tun kẹdun iku iyawo olori ọmọ ogun oju ofurufu nigba kan ri, Admiral Ọla Sa'ad Ibrahim, Hajia Aminat Dupẹ.


Hajia Aminat Dupe jade laye lalẹ ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii.

AbdulRazaq ṣapejuwe iku obinrin naa gẹgẹ bi eyi to ba ni lọkan jẹ.

O ba awọn mọlebi oloogbe naa kedun, to si gbadura pe ki Ọlọrun mu wọn lọkan le.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI