Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti kede Ọjọgbọn Shuaib Ọba Abdulraheem gẹgẹ bii alakoso agba ati alaga igbimọ iṣakoso fasiti ipinlẹ naa, Kwara State University of Education (KWSUED).
Ọba Abdulraheem ni yoo maa lewaju igbimọ iṣakoso fasiti tuntun ti gomina buwọ lu naa, fun idagbasoke eto ẹkọ nipinlẹ Kwara.
Lara awọn ọmọ igbimọ iṣakoso fasiti tuntun ọhun ni; Arabinrin Ọpaleke Bukọla Iyabọ; Hajia Risikat Lawal; Rotimi Samuel Olujide; Ọjọgbọn Umar Gunu; Onimọ-ẹrọ Saad Belgore; Ọgbẹni Fẹmi Aina; Ọmọwumi Amuda; Hajia Kubra Kazum; Ọjọgbọn Ibrahim Abdukadir Abikan; to fi mọ awọn aṣoju ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ nipinlẹ naa.
Nigba to n gba awọn alakoso igbimọ ọhun lamọran, Gomina Abdulrazaq sọ pe igbesẹ ọtun tuntun ree ninu fasiti , ti wọn si gbọdọ ṣe ohun to tọ lati mu idagbasoke ati itẹsiwaju ba a.
AbdulRazaq sọ pe ọmọ tuntun ni fasiti naa jẹ, to si ni idari ati itọni lati dagbasoke ninu eto ẹkọ ati ilana to tọ.
AbdulRazaq sọ pe ọmọ tuntun ni fasiti naa jẹ, to si ni idari ati itọni lati dagbasoke ninu eto ẹkọ ati ilana to tọ.
Siwaju sii lo ni fasiti ọhun tun jẹ iṣakoso tuntun to gba ipo lọwọ kọlẹẹji to wa tẹlẹ lati le maa lewaju.
Bakan naa ni gomina tun kede Olupo tiluu Ajaṣẹ-Ipo, Ọba Ismail Yahya Alebioṣu gẹgẹ bii giwa agba patapata fun fasiti naa.
Lara awọn to wa nibi eto ati ayẹyẹ ifilọlẹ ọhun ni alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni Kwara, Ọmọọba Sunday Fagbemi; igbakeji olori awọn oṣiṣẹ gomina, Ọmọọbabinrin Bukọla Babalọla; Kọmiṣanna feto ẹkọ agba, Ọmọwe Mary Arinde; oludamọran agba pataki, Sa'adu Salau.
Awọn miran ni Alaaji Abdulrazhaq Jiddah to jẹ oludamọran pataki fun gomina lori akanṣe iṣe ode; oludamọran agba pataki lori ẹsin Isilaamu, Ibrahim DANMAIGORO; ati akọwe agba nileeṣẹ eto ẹkọ agba, Amofin Sabitiyu Kikelomo Grillo, to fi mọ awọn miran.
Ninu ọrọ rẹ, Ọmọwe Arinde gbe oṣuba kare fun gomina lori afojusun rere rẹ fun eto ẹkọ, eyi to bi fasiti tuntun naa..
O ni igbesẹ tuntun naa ti fi apẹẹrẹ rere lelẹ nipa itẹsiwaju afojusun ati erongba rere fun fasiti naa, ati agbekalẹ ọjọ iwaju rere fun eto ẹkọ.
No comments:
Post a Comment