Lojuna lati ba opopona agbaye mu, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bẹrẹ atunṣe agbegbe layipo Ọmọda si Ọja Ọba fun irọrun araalu.
Igbesẹ yii jẹ ọkan lara awọn ipinnu ati erongba Gomina AbdulRazaq lati mu ki ipinlẹ Kwara fa awọn oludokoowo agbaye mọra fun eto ọrọ aje onitẹsiwaju.
Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Ọlayinka Fafoluyi fi sita laipẹ yii, o ni ọpọ opopona ni gomina ti so papọ lati bi ọdun marun sẹyin.
Fafoluyi jẹ ko di mimọ pe ọpọ agbegbe to jẹ inu igbo ni gomina ti sọ di opopona fun igbokegbodo ọkọ to ja geere lati ṣe amugbooro ba eto ọrọ aje Kwara.
No comments:
Post a Comment