Eto ẹkọ yoo bẹrẹ ni pẹrẹu ni fasiti KWASU loṣu kinni, ọdun 2025 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 18, 2024

Eto ẹkọ yoo bẹrẹ ni pẹrẹu ni fasiti KWASU loṣu kinni, ọdun 2025


Orin, ilu ati ijo l'awọn ara agbegbe ìjọba ibilẹ Guusu ati Ariwa Kwara fi n yọ nigba ti wọn gbọ pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti pari kikọ ọgba fasiti ipinlẹ naa, KWASU to wa ni Osi ati Ilesha Baruba.
 
Inu oṣu kinni, ọdun 2025 la gbọ pe eto ẹkọ yoo bẹrẹ lakọtun pẹlu ilana eto ẹkọ mẹfa ọtọọtọ.

Ijọba Kwara ko fi iṣẹ naa falẹ rara, pẹlu bi awọn agbaṣẹṣe ṣe n jara mọṣẹ, gẹgẹ bi awọn alakoso ṣe sọ lopin ọsẹ to kọja yii.

Bo tilẹ jẹ pe iṣakoso to kọja lo bẹrẹ iṣẹ naa, sibẹ, Gomina AbdulRazaq ti ṣeleri, to si fọkan awọn araalu balẹ wi pe iṣakoso oun ko nii pa iṣẹ akanṣe kankan ti.

Ọmọwe Mary Arinde to jẹ Kọmiṣanna feto ẹkọ giga nipinlẹ Kwara sọ fawọn akọroyin pe iṣẹ kikọ ile-ẹkọ ọhun ni ijọba ibilẹ Osi ati Ekiti ti de ipele ida mejidinlaadọrun-un ko pari.

Ọmọwe Arinde jẹ ko di mimọ pe awọn ti n gbaradi lati bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹu fun saa ikẹkọọ ọdun 2024 si 2025.

Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe awọn akẹkọọ ni ẹka ikẹkọọ Fine and Applied Arts ni labẹ ẹka Environmental Sciences yoo bẹrẹ sii kẹkọọ ni ọgba Osi lati ọjọ kejidinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2024.

Bakan naa lo ni awọn akẹkọọ ni ẹka ikẹkọọ iṣẹ agbẹ ati ọgbin (Agriculture) yoo bẹrẹ iṣẹ ni ọgba Ilesha Baruba ninu oṣu kinni, ọdun 2025.

Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe ilana eto ẹkọ miran ti yoo bẹrẹ lọdun 2025 ni: Estate Management, Urban and Regional Development, Geography, Architecture, Quantity Survey and Building, ati awọn miran.

Aworan ibi ti iṣẹ de






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI