Emir Ilọrin rọjo adura le Gomina AbdulRazaq lori tinutinu, o lo n mu inu oun dun ni gbogbo igba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 12, 2024

Emir Ilọrin rọjo adura le Gomina AbdulRazaq lori tinutinu, o lo n mu inu oun dun ni gbogbo igba


Emir tiluu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari ti finufẹdọ rọjo adura le Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara lori.

Ọmọwe Sulu-Gambari lo ṣe eyi lasiko to n ṣayẹyẹ ayajọ ọdun mọkandinlọgbọn to de ori ipo naa.

Emir ni ọkan pataki lara awọn to n gbe aṣa ati iṣe ilu Ilọrin larugẹ ni gbogbo igba ati ni gbogbo ọna ni Gomina AbdulRazaq jẹ.

Bakan naa ni Emir tun rọ awọn agba ẹsin lati fọwọsowọpọ ṣe adura fun Sardauna tiluu Ilọrin naa fun akitiyan ati ipa to n ko ninu idagbasoke ipinlẹ Kwara, paapaa ilu Ilọrin.

O ni ki Ọlọrun tubọ maa fun gomina ni ọgbọn, imọ ati oye lati maa fi mu ilọsiwaju ba ilẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI