“Ijọba yii wa fun gbogbo eeyan, to fi mọ awọn ọmọ bibi ati olugbe ilu Igbomina ti kii ṣe pe wọn kan wa ninu ijọba nikan, ṣugbọn ti wọn ti jẹ anfaani alailẹgbẹ ninu agbekalẹ idagbasoke ilu ati igberiko kaakiri.”
Wọnyi ni ọrọ ti Gomina Abdulrahman Abdulrazaq sọ nibi ayẹyẹ ọdun Ọmọ Igbomina, ẹlẹẹkẹtala iru rẹ to waye laipẹ yii niluu Iludun Oro.
Ọpọ wakati ni Gomina Abdulrazaq lo lati fi ba wọn ṣe ayẹyẹ naa lagbegbe ẹkun Guusu ipinlẹ Kwara.
Nibi ayẹyẹ ọhun ni gomina ti gbe oriyin fun awọn ọmọ Igbomina pẹlu ọkan akikanju mo-le-ṣe-e ti wọn n lo lati fi mu ki aṣa ati iṣe wọn maa tẹsiwaju nipa riran ara wọn lọwọ, eyi to ti ṣapejuwe awọn aṣey]ori wọn lẹka eto ẹkọ ati idaṣẹsilẹ.
Bakan naa ni gomina tun pe gbogbo ọmọ ilu ati olugbe ilu Igbomina lati tubọ maa gba alaafia laaye, ki wọn si jinna si ẹlẹyamẹya , lati le ṣagbelarugẹ fun iṣọkan apapọ ati idagbasoke.
Bẹẹ lo dupẹ fun igbaruku ti wọn si iṣakoso rẹ ni gbogbo ọna, to si ṣeleri pe oun yoo tubọ maa ṣe iranlọwọ to ba yẹ fun wọn.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ olori ọba ilẹ Igbomina lapapọ, Ọba Ismaila Yahaya Alebioṣu, Olupo tiluu Ajaṣẹ Ipo fun aduroti si ijọba rẹ.
Gomina ni lara awọn akanṣe iṣẹ toun ti ṣe ni ti atunṣe awọn opopona bii Arandun-Esie-Oro; Owu Fall; Afara Orisa, Oro Ago; Omu Aran Oko; Owode Ofaro-Alabe; ati Ajase-Ipo Okeiya; to fi mọ awọn miran.
Ọpọ awọn eekan-eekan nipinlẹ Kwara bii igbakeji gomina, Kayọde Alabi ti Ọtunba Biọdun Ajiboye ṣoju fun; Sẹnetọ Saliu Mustapha ti Amofin Abdulkareem Alabi ṣoju fun; Sẹnetọ Lọla Ashiru; Sẹnetọ Sadiq Umar; Ọnarebu Raheem Ajulọ-opin; Elese tiluu Igbaja, Ọba Ahmẹd Babalọla Awuni (Arepo II); Olomu tiluu Omu Aran, Ọba Abdulraheem Ọladele Adeoti lo wa nibẹ.
Awọn miran ni Olupako tiluu Share, Ọba Haruna Ọlawale Sulyman; Oloro tiluu Oro, Ọba Joel Ọlaniyi Ọyatoye; to fi mọ awọn oludasilẹ fasiti Al-Hikmah, to tun jẹ alaga ọjọ naa, Oloye Ọladimeji Igbaja; alaga apapọ fọmọ Ibilẹ Igbomina, Alagba Gabriel Yẹmi Jimoh; ati Oloriewe Raheem Adedoyin; ati awọn miran.
Ninu iroyin miran to fara pẹ ẹ, Gomina AbdulRazaq kopa nibi eto ayẹyẹ Maulid nabbiy to waye niluu Ọffa, nibi ti Imaamu agba, Sheikh Muhyideen Salman Hussein ti gba a lalejo.
Nibẹ ni gomina ti pe fun adura fun orileede Naijiria, to si bẹ awọn araalu lati maa dupẹ fun aanu Ọlọrun ti wọn n ri gba nin gbogbo ọna.
No comments:
Post a Comment