Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede wi pe ohun ko nii san owo oṣu, ti oṣu kọkanla fun awọn oṣiṣẹ ti ko ba ti ni nọmba idanimọ tijọba, iyẹn KWSRRA.
Ninu atẹjade ti Babatunde Toyin Abdulrasheed to jẹ akọwe iroyin ileeṣẹ to n ri sọrọ eto iṣuna fi sita, o ni o ṣe pataki pupọ fun oṣiṣẹ lati ni n
Ijọba sọ pe gbogbo oṣiṣẹ lo pan dandan fun lati ni nọmba idanimọ olugbe ipinlẹ Kwara, eyi to ti bẹrẹ lati ọpọ oṣu sẹyin.
Wọn ni bẹrẹ lati ipari oṣu kọkanla ti a wa yii ni wọn yoo gbegi dina owo oṣu ati ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ to ba kọ lati ni nọmba idanimọ ọhun.
Kwara State Residents Registration Agency (KWSRRA) ni won pe orukọ nọmba naa, leyi to wa fun awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara.
Gbogbo olugbe lo si pọn dandan fun lati gba akanṣe nọmba naa fun eto ati ilana ijọba nipa eto aabo, ṣiṣe ojuṣe faraalu ati awọn nnkan miran.
Atẹjade ọhun ti kọmiṣanna feto iṣuna, Ọmọwe Hauwa Nuru buwọlu ṣalaye pe gbogbo oṣiṣẹ ijọba kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun ni wọn gbọdọ gba nọmba naa.
O ni ẹnikẹni to ba kọ lati gba a titi digba ti ijọba yoo bẹrẹ sii san owo oṣu, ko nii lẹtọ lati gba owo oṣu ati ajẹmọnu to ba yẹ.
No comments:
Post a Comment