Alaga ẹgbẹ awọn gomina lorileede Naijiria, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ṣapejuwe Oloogbe Ọgagun Taoreed Abiọdun Lagbaja gẹgẹ bi aṣaaju rere to ja fun ilẹ naa.
Gomina AbdulRazaq sọ pe akikanju ti ipa rere rẹ yoo maa jẹ iranti fun gbogbo ọmọ Naijiria titilai ni Oloogbe Lagbaja.
Ninu atẹjade ti oludamọran pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Ọlayinka Fafoluyi fi sita, gomina ni awọn yoo ṣafẹri gidigidi nipinlẹ Kwara.
AbdulRazaq sọrọ naa nibi eto isin idagbere ti wọn ṣe fun Oloogbe Lagbaja ni gbọngan apapọ awọn Kristẹẹni to wa niluu Abuja.
O ni ọmọ Naijiria rere to fi ara jim fun isọkan orileede Naijiria, ati alaafia to fi mọ eto aabo papọ ni oloogbe naa.
Alẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun-un, oṣu kọkanla, ọdun 2024 ni Ọgagun Taoreed Abiọdun Lagbaja dagbere faye, lẹyin aisan rampẹ.
No comments:
Post a Comment