Ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣe ikilọ fun awọn to n fi ẹbun oṣelu ta awọn ile ẹkọ lọrẹ.
Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna fero ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan nipinlẹ naa, Hajia Sa'adatu Moddibo Kawu gbe jade laipẹ yii, o ni ki awọn oloṣelu dẹkun iwa naa.
Ijọba ni bo tilẹ jẹ pe ohun ko lodi si ki awọn eeyan tabi ajọ maa fi ẹbun ta ile ẹkọ lọrẹ, nipa ṣiṣe iranwọ, sibẹ ko nii boju mu lati maa fi awọn ẹbun to jẹ ti oṣelu ta wọn lọrẹ.
“Iwa yii, to nii ṣe pẹlu yiya aworan eeyan sara iwe tabi ohun elo ile ẹkọ lati fi ṣafihan ẹni to fi ta ile ẹkọ lọrẹ ni lati dawọ duro.
“Nigba ti a tẹwọ gba iranwọ fun awọn ile ẹkọ ijọba, ti a si mọ riri rẹ, ijọba ni ilana ati ofin lori igbesẹ naa, ati pe. Ko gbọdọ si aworan to polongo oṣelu ninu ẹbun yoowu ti wọn le fẹẹ fi ta awọn akẹkọọ ile ẹkọ ijọba lọrẹ.
“O wa ni akọsilẹ pe gbogbo awọn ẹbun to jẹ ohun elo ikẹkọọ ti ijọba pin fawọn ile ẹkọ laaarin ọdun 2019 titi di asiko yii ko ni aworan gomina ninu, ẹni to ro pe awọn iwa naa ko dara to fawọn ọmọde.
“Awọn oṣiṣẹ ijọba ati aladani nii lati mọ eyi daju. Bakan naa, ijọba dupẹ lọwọ gbogbo awọn to n fi ẹbun ta awọn ile ẹkọ ijọba lọrẹ.”
No comments:
Post a Comment