Baltasar Engonga dero atimọle lori ẹsun ibalopọ pẹlu irinwo obinrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 10, 2024

Baltasar Engonga dero atimọle lori ẹsun ibalopọ pẹlu irinwo obinrin


Alakoso agba  fun ajọ to n ri si iwadii eto iṣuna apapọ,
National Financial Investigation Agency, lorileede Equatorial Guinea, Baltasar Engonga ti dero atimọle lori ẹsun biba obinrin rẹpẹtẹ lajọṣepọ.
 
Ajọ ANIF ni wọn ti fọwọ osi juwe ile fun Engonga lori ẹsun iwa jibiti, ṣaaju asiko ti aṣiri awọn fọnran naa jade sita.

Ọgba ẹwọn Malabo’s Black Beach ni wọn ju Engonga si.
 
Ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin naa ni ti ibalopọ to lagbara julọ ninu itan orileede naa.
 
Ọpọ awọn obinrin ti wọn jẹ iyawo awọn gbajumọ to fi mọ awọn ilu mọn-ọn-ka obinrin lorileede naa la gbọ pe o ba lajọṣepọ, to si ṣe fọnran wọn pamọ.
 
Iṣẹlẹ ọhun lo mu ki aarẹ ilẹ Equatorial Guinea, Obiang Nguema Mbasogo jawe lọ gbele ẹ fun Engonga.
 
Ẹsun iwa jibiti ati ikowojẹ ni Engonga yoo koju nigba to ba bẹrẹ sii foju ba ile-ẹjọ, gẹgẹ bi iroyin ayelujara ilẹ Faranse, Afrikmatin ṣe gbe e jade.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI