Awọn eeyan fẹ ki ijẹgaba Man City dopin - Guardiola sọrọ soke - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 10, 2024

Awọn eeyan fẹ ki ijẹgaba Man City dopin - Guardiola sọrọ soke


Akọnimọ-ọn-gba ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City, Pep Guardiola ti sọ pe erongba awọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ ere bọọlu kaakiri agbaye ni pe ki ijẹgaba ẹgbẹ agbabọọlu oun dopin.
 
Guardiola sọrọ naa lẹyin ti Man City padanu sọwọ akẹgbẹ wọn ti Brighton ninu idije Premier League to waye lọjọ Abamẹta to kọja.
Ọmọ ilẹ Spain naa sọ pe oun nifẹ si adojukọ, bo tilẹ jẹ pe iyẹn ko ni koun rẹwẹsi lati tẹsiwaju.

Brighton lo pada bori Man City pẹlu aami ayo meji si ẹyọkan ni papa iṣere Falmer Stadium.

“Mo nifẹ si adojukọ. Nko ni pada sẹyin, mo ṣi n fẹ bori sii.

“Awọn eeyan n fẹ ki ijẹgaba wa dopin, ṣugbọn... a ko tii pari sibẹ.”

Guardiola lo gbe ikọ Man City lati gba ife ẹyẹ Premier League fun igba mẹfa laarin ọdun meje sẹyin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI