Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti ki Gomina Lucky Aiyedatiwa ku oriire bo ṣe jawe olubori ninu eto idibo gomina to waye nipinlẹ Ondo lopin ọsẹ to kọja.
Aiyedatiwa ni ajọ eleto idibo ni Naijiria, ẹka tipinlẹ Ondo kede gẹgẹ bi ẹni to ṣe ipo kinni ninu eto idibo gomina to waye kọja, ti ijawe olubori rẹ si tayo eyikeyi awọn alatako rẹ.
Nigba to n sọrọ, Gomina Abiọdun toun naa wa nibi ti ajọ INEC ti kede esi ibo to gbe Aiyedatiwa wọle gẹgẹ bii gomina fun igba akọkọ sọ pe aṣeyọri nla ni, ati pe idibo naa fi han pe awọn araalu ṣi nigbagbọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
Bakan naa lo tun sọ pe aṣeyọri naa fi han daju pe ipa rere ni ẹgbẹ oṣelu APC n ko ninu eto idagbasoke ati ilọsiwaju nipinlẹ Ondo.
No comments:
Post a Comment