Aarẹ Tinubu dagbere fawọn ọmọ Naijiria bo ṣe gba Brazil lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 18, 2024

Aarẹ Tinubu dagbere fawọn ọmọ Naijiria bo ṣe gba Brazil lọ


Lọjọ Aiku to kọja yii ni Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu fi orileede Naijiria silẹ lọ si Brazil, nibi akanṣe ipade awọn adari ti wọn pe ni G20 Leaders’ Summit, ikọkandinlogun iru ẹ.
 
Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Bayọ Ọnanuga lo fi iroyin ọhun lede, to si ni Aarẹ Luiz Inacio Lula da Silva ti orileede Brazil, ẹni to tun jẹ aarẹ ẹgbẹ naa lo ṣagbatẹru irin ajo ọhun.
 
Eyi si lo waye lẹyin ọjọ marun-un ti Aarẹ Tinubu de lati ilẹ Saudi Arabia.
 
Ninu atẹjade ti Ọnanuga fi sita, o ṣalaye pe “Aarẹ Tinubu yoo kuro niluu Abuja lọ si  Rio de Janeiro ti ilẹ Brazil lọjọ Aiku fun akanṣe ipade awọn alakoso ti G20 Leaders’ Summit, ikọkandinlogun iru ẹ to n waye ni Guusu ilẹ Amẹrika.”
 
O fi kun ọrọ rẹ pe ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun si ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kọkanla ni ipade ọhun yoo fi waye, nibi ti awọn adari ogun lagbaye yoo ti waye.
 
Bakana naa lo jẹ ko di mimọ pe akori ipade tọdun yii ni wọn pe ni  ‘Building a Just World and a Sustainable Planet,’ nibi ti wọn yoo ti jiroro lori ọna abayọ lati gbogun ti iṣẹ ati oṣi, ayipada nibi eto iṣejọba agbaye ati imugbooro ba eto iṣipopada agbara.
 
Lara awọn to kọwọrin pẹlu aarẹ ni minisita fọrọ ilẹ okeere, Ambassador Yusuf Tuggar; minisita fọrọ idagbasoke ohun ọsin, Idi Mukhtar Maiha; minisita fọrọ aṣa ati irin ajo afẹ, Hannatu Musawa; minisita fọrọ iṣẹ agbẹ ati aabo lori ounjẹ fun ipinlẹ, Ọmọwe Aliyu Sabi Abdullahi ati alakoso agba fun ajọ National Intelligence Agency, Ambassador Mohammed Mohammed.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI