Ounjẹ yanturu ni Kwara, irọrun ọmọ Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 17, 2024

Ounjẹ yanturu ni Kwara, irọrun ọmọ Naijiria


Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ bayii, ipinlẹ Kwara ti n wa lara awọn ipinlẹ ti yoo fọkan ọmọ Naijiria balẹ nipa ipese ounjẹ, paapaa irẹsi ti awọn eeyan n jẹ julọ.

Ipinlẹ Kwara lasiko yii ti ni ọpọ ilẹ ti wọn fi da oko irẹsi si, ti aabo si wa fun un.

Ahere idakosi (farm clusters) to le ni ọgọrun kan to wa laarin ogun ẹkita (20 hectares) si ẹgbẹrun marun-un ẹkita (5,000 hectares) ni ijọba ti pese silẹ lati fi gbogun ti iṣẹ ati oṣi.

Ahere kan ti wọn n pe ni Rogun, eyi to wa niluu Patigi naa jẹ ọkan pataki lara awọn ahere tijọba Kwara ya sọtọ fun iṣẹ agbẹ, paapaa nipa oko dida.

Awọn agbẹ to n gbin irẹsi lati Rogun, iyẹn ni wọọdu keji, ijọba ibilẹ Patigi wa lara awọn to jẹ anfaani ijọba nipa ohun ọgbin ti wọn gba.

Eyi si ni igbesẹ to bẹrẹ lati gbogun ti ebi ọgaja-fọwọmẹkẹ.








No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI