Ọmọ 'Yahoo' mẹrinlelogun ha sọwọ EFCC l'Ẹdo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 2, 2024

Ọmọ 'Yahoo' mẹrinlelogun ha sọwọ EFCC l'Ẹdo


Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka tiluu Benin ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi mẹrinlelogun lori ẹsun jibiti ori ayelujara.
 
Ilu Benin to wa nipinlẹ Ẹdo ni ajọ EFCC ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gbogbo wọn lasiko ti wọn n jaye familete-ki-n-tutọ lọwọ.
 
Ninu atẹjade ti EFCC gbe soju opo 'X' wọn laipẹ yii, wọn jẹ ko di mimọ pe agbegbe ọtọọtọ lọwọ ti tẹ wọn.
 
Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe mọto ayọkẹlẹ bọginni mọkanla, ẹrọ kọmputa alagbeka, foonu olowo nla loriṣiriṣi ati ẹgbẹrun lọna ọgọjọ naira ni wọn gba lọwọ wọn lasiko tọwọ tẹ wọn.
 
EFCC tẹsiwaju pe gbogbo awọn tọwọ tẹ naa ni wọn ti ṣe akọsilẹ awọn ohun to le ran iṣẹ iwadii wọn lọwọ ni kikun, ati pe wọn yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iṣẹ iwadii ba tubọ pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI