Giwa fasiti iṣẹ agbẹ ati ọgbin, Federal University of Agriculture (FUNAAB) to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Babatunde Kẹhinde ti pe fun ifọwọsowọpọ araalu lojuna lati gbogun ti ebi, iṣẹ ati oṣi, paapaa iyan.
Ọjọgbọn Kẹhinde sọ pe ojuṣe gbogbo araalu ni lati pawọpọ gbogun ti iyan, nipa pipese ounjẹ ti yoo pọ yanturu lai duro de ijọba, paapaa lasiko ipenija to n koju orileede Naijiria.
Akọṣẹmọṣẹ Ọjọgbọn naa sọrọ yii nibi eyo akanṣe ijiroro ti ajọ Nigerian Institute of Public Relations (NIPR), ẹka ti ipinlẹ Ogun ṣagbekalẹ rẹ niluu Abẹokuta.
Gbọngan aṣa ti June 12 to wa ni Kutọ, Abẹokuta ni eto ọhun ti waye lọjọ Ẹti, ọsẹ yii.
Ọjọgbọn Kẹhinde sọ pe lojuna lati de ilẹ ileri afojusun ajọ iṣọkan agbaye, iyẹn United Nations' Sustainable Development Goals (SDGs) nipa ọrọ ebi, afi ki araalu ni ifọwọsowọpọ.
Nigba to n sọrọ lori akori eto naa ti wọn pe ni "Galvanising Public and Private Stakeholders Toward Addressing Food Crisis in Nigeria: Public Relations as Key Driver," Ọjọgbọn Kẹhinde gbe oriyin fun ajọ NIPR lori bi wọn ṣe mu ọrọ aabo ounjẹ lọkunkundun ninu ohun ijiroro wọn.
Agba Ọmọwe naa tẹsiwaju pe lati yanju iṣoro aisi eto aabo lori ounjẹ, o gba ajọṣepọ laarin ile ẹkọ, ijọba ati awọn ileeṣẹ aladani nipa agbekalẹ eto to munadoko lati daabobo ọjọ iwaju iṣẹ agbẹ ati ọgbin lorileede Naijiria.
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe kii ṣe ojuṣe ile ẹkọ FUNAAB ni lati bọ orileede Naijiria, bi ko ṣe lati ro awọn akẹkọọ lagbara nipa agbekalẹ ọna ti wọn le gba lati ran ilẹ naa lọwọ nipa iṣẹ agbẹ ati ọgbin.
Ṣaaju asiko yii ni Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun, ẹni ti Kọmiṣanna feto iṣẹ agbẹ ati ọgbin, Ọnarebu Bolu Owotọmọ ṣoju fun yananaa awọn idojukọ Naijiria lori aisi eto aabo lori ounjẹ.
Ọnarebu Owotọmọ jẹ ko di mimọ pe ọna abayọ si iṣoro naa kọja agbara ijọba, to si ni o gba ajọṣepọ laarin awọn aladani ati ijọba, ati pe anfaani naa gbọdọ jẹ eyi ti yoo mu iwuri ba araalu.
Bakan naa, ṣaaju ninu ọrọ ikinikaabọ rẹ, alaga ajọ NIPR nipinlẹ Ogun, Arabinrin Oluwaṣeun Boye ṣapejuwe eto ijororo naa gẹgẹ bii ipe lati gbe igbesẹ to yẹ, ati lati ṣi oju ijọba ati araalu si ọna abayọ iṣoro ebi.
No comments:
Post a Comment