Ijọba ipinlẹ ti ṣe ileri wi pe gbogbo awọn opopona to wa kaakiri ipinlẹ naa ni wọn yoo ṣe ni ti igbalode fun lilo ọjọ pipẹ ti yoo maa mu eto ọrọ aje lọ soke.
Kọmiṣanna f'ọrọ iṣẹ ode ati igbokegbodo ọkọ, Onimọ-ẹrọ Abdulquawiy Olododo lo sọ eyi di mimọ laipẹ yii niluu Ilọrin lasiko abẹwo to ṣe lọ sawọn agbegbe ti iṣẹ ti n lọ.
Nibẹ lo ti ṣalaye pe agbegbe aarin gbungbun ipinlẹ Kwara yoo jẹ ibi amojuto fun opopona to ja geere lati mu idagbasoke nla ba a.
Onimọ-ẹrọ Olododo jẹ ko di mimọ pe awọn ti n rii daju pe awọn agbaṣẹṣe n tẹpa mọ iṣẹ ti ijọba gbe le wọn lọwọ.
Lara awọn to kọwọrin pẹlu rẹ ni Onimọ-ẹrọ Ladi Yusuf, amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori idagbasoke iṣẹ ode.
Olododo sọ pe awọn nilo akanṣe iṣẹ ti yoo ba ti agbaye figagbaga, ati pe awọn gbọdọ ṣe e lai jafara.
No comments:
Post a Comment