Ọba alaye meji gbọpa aṣẹ ni Kwara lọjọ kan ṣoṣo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 28, 2024

Ọba alaye meji gbọpa aṣẹ ni Kwara lọjọ kan ṣoṣo


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gbe ọpa aṣẹ ati iwe ẹri le ọba alaye tuntun meji ọtọọtọ lọwọ lọjọ kan ṣoṣo.
 
Ọba Joel Ọyatoye Titiloye ati Gbamoyin tiluu Jimba-Ọja, Ọba Adebayọ Ọlanrewaju Ismail ni awọn ọba alaye naa

Nigba to n gbe ọpa aṣẹ ati iwe ẹri le awọn ọba tuntun naa lọwọ, igbakeji gomina, Kayọde Alabi gba wọn lamọran lati lo ipo wọn daadaa.

O ni ki wọn rii daju pe ipo tuntun yii, wọn loo lati fi gbe ifẹ, iṣọkan, alaafia ati ilọsiwaju ilu larugẹ.

Siwaju sii lo rọ awọn ọmọ ati olugbe ilu Oro ati Jimba-Ọja lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọba wọn, ki alaafia, iṣọkan ati ifẹ le maa jọba.
















No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI