NNPC kede afikun owo ori jaala epo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 9, 2024

NNPC kede afikun owo ori jaala epo


Ajọ to n ṣabojuto epo rọbii lorileede Naijiria, Nigerian National Petroleum Company Limited, NNPCL ti kede afikun lori owo ori jaala epo bẹntiroolu kaakiri ilẹ yii.
 
NNPC sọ pe ẹgbẹkan le ni ọgbọn naira, N1,030 ni awọn yoo maa ta jaala epo bẹntiroolu bayii.

Igbesẹ naa lo ti bẹrẹ bayii kaakiri awọn ile itapo NNPC niluu Abuja, lonii, Ọjọru.

Eyi lo si waye lẹyin ti adehun ileeṣẹ NNPCL ati ileeṣẹ Dangote fori ṣanpọn laipẹ yii.

NNPCL sọ pe awọn ko le jẹ alarena laarin ileeṣẹ ifọpo Dangote ati awọn alagbata mọ, nitori pe adehun wọn ko wọ.
 
Ọtadinlọgọrun mẹsan, N897 naira ni ileeṣẹ NNPC n ta epo tẹlẹ niluu Abuja, ti wọn si n ta ni N885 lawọn ipinlẹ miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI