Mo mọ pe nko le yege ninu idije Ballon d’Or - Vinicius Jr sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 28, 2024

Mo mọ pe nko le yege ninu idije Ballon d’Or - Vinicius Jr sọrọ


Gbajugbaja agbabọọlu ọwọ iwaju fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid, Vinicius Junior ti sọ pe oun ko ṣetan lati kopa ninu idije Ballon d'Or ti yoo waye lalẹ oni, ọjọ Aje, Mọnde.

Bakan naa ni ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid sọ pe oun ko nii ran eyikeyi ninu agbabọọlu wọn fun eto ọhun.

LaLiga naa mọ pe wọn ko nii kede Vinicius gẹgẹ bi ẹni ti yoo jawe olubori.

Gbajugbaja nni lori tita ati rira agbabọọlu, Fabrizio Romano lo sọrọ naa jade.

Romano ninu ọrọ to kọ soju opo 'X' rẹ sọ pe Vinicius Jr ko nii rin irin ajo lọ si Paris gẹgẹ bi Real Madrid ṣe mọ pe ko nii yege fun Ballon d’Or.

“Ko sẹnikẹni lati Real Madrid to maa kopa nibi eto ayẹyẹ naa.

“Ko si Florentino Pérez, ko si Vini Jr, ko si Carlo Ancelotti, ko si Jude Bellingham.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI