Ọkan pataki lara awọn anfaani alailẹgbẹ ti ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited maa n ṣagbekalẹ rẹ, paapaa lasiko ti ọdun tuntun ba n bọ bayii ni ti Lemon Friday Promo.
Ko lonka lawọn onibara to ti jẹ anfaani ti ko wọpọ yii pẹlu oriṣiriṣi ẹbun ọlọkan-o-jọkan, paapaa awọn to nifẹẹ lati dokoowo lori ọrọ ile gbigbe.
Anfaani ọtun ti ileeṣẹ Adron Homes wa ṣagbekalẹ rẹ yii lo yatọ patapata si awọn eyi ti wọn ti gbe jade pẹlu ẹdinwo ara ọtọ.
Wọnyi ni koko pataki mẹfa ti o nilo lati mọ
Anfaani ẹdinwo lori gbogbo dukia
Adron Lemon Friday Promo fi anfaani ti ko wọpọ sita lori gbogbo awọn dukia bii ile gbigbe, ilẹ tita sibi to jọju. Anfaani perete lo wa nilẹ fun awọn onibara to ba n fẹ ọjọ iwaju rere funra wọn.
Sisan owo lọna irọrun
Lara awọn ohun to maa n mu ki ọkan awọn eeyan balẹ ni ti rira ọja, ko si wa ri anfaani lati maa san owo naa diẹdiẹ lọna ti ko ga ni lara. Anfaani yii wa nilẹ nileeṣẹ Adron Homes.
Anfaani naa wa fun onibara lati san owo fun ọgọta oṣu tabi ọpọ ọdun, ti yoo si nii ṣe pẹlu anfaani eyi to ba nawọ gan.
Awọn ẹbun to joju ni gbese
Awọn onibara le kopa ninu anfaani eto 2024 Lemon Friday Promo yii nipa sisan ida marundinlaadọta siwaju, ko too fi ọgọta oṣu san owo yooku pẹlu irọrun. Si afikun, onibara yoo lanfaani si oniruuru ẹbun iwuri bii baagi irẹsi, batiri ẹrọ amunawa agboorun, maalu ati awọn miran.
Agbegbe, agbegbe, agbegbe to jọju ni gbese
Bi eeyan ba fẹẹ pẹ laye, agbegbe to ba yan laayo lati gbe ni yoo sọ irufẹ igba ati akoko to maa lo laye. Idi ree ti ileeṣẹ Adron Homes fi da yatọ pẹlu awọn agbegbe ti ilẹ ati dukia wọn wa kaakiri Naijiria bii Eko, Ibadan, Abuja, Ogun, Ọṣun, Ekiti, Jos, Nasarawa ati awọn miiran.
Awọn iwe ẹri ati iwe aṣẹ to jẹ ojulowo
Rira dukia tabi ilẹ nii ṣe pẹlu gbigba oriṣiriṣi iwe ẹri ati iwe aṣẹ, ṣugbọn ni ileeṣẹ Adron Homes, irọrun lo ba de nitori pe gbogbo rẹ lo ti wa nilẹ ni kikun. Lati ori iwe ilẹ ati dukia, titi de ori awọn iwe ijọba to jẹ ojulowo ni onibara yoo tẹwọgba ni kete ti wọn ba san owo tan.
Anfaani si ọrọ amọran lati ọdọ awọn akọṣẹmọṣẹ
Lara awọn ohun to n mu ki irin ajo aye ẹni ja geere ni ti riri awọn oludamọran pataki ti n tọni sọna. Awọn wọnyi lo wa nileeṣẹ Adron Homes lati tọ awọn onibara sọna to yẹ, ki wọn ma ba a ṣi ẹsẹ gbe.
Ẹ kan si eyikeyi oju opo ayelujara Adron Homes fun ẹkunrẹrẹ alaye tabi ibeere, bẹẹ si lẹ le wọ eyikeyi ọfiisi wọn to ba wa ni arọwọto yin
No comments:
Post a Comment