Kasnaty Sugar, gbajugbaja sọrọsọrọ fẹẹ ko awọn arugbo lọ wẹ lodo igbalode lọsẹ yii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 7, 2024

Kasnaty Sugar, gbajugbaja sọrọsọrọ fẹẹ ko awọn arugbo lọ wẹ lodo igbalode lọsẹ yii


Gbogbo eto lo ti pari patapata fun ogbontarigi gbajugbaja pedepede lori redio ati tẹlifiṣan, Kọlawọle Atanda Adejojo lati ko awọn arugbo lọ wẹ lodo igbalode niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Adejojo ti awọn ololufẹ rẹ mọ si Kasnaty Sugar kaakiri agbaye lo fidi eyi mulẹ ninu atẹjade to fi sita laipẹ yii.

Ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Ọṣun to fi ilu Abẹokuta ṣe ibugbe naa sọ pe ọkan ọna lati maa mu inu awọn agbalagba, paapaa awọn arugbo dun ni igbesẹ naa jẹ.

Odo igbalode ti a mọ si 'swimming pool', ti ile itura Daktad to wa lagbegbe Quarry Road, niluu Abẹokuta ni eto ọhun yoo ti waye l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii, iyẹn ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2024.


Odu ni Kasnaty Sugar, kii ṣaimọ foloko, paapaa to ba di titọju arugbo kaakiri orileede Naijiria.

Kasnaty Sugar ti ko arugbo lọ sori Oke Olumọ, o ti ṣagbekalẹ eto iranwọ fun wọn, bẹẹ lo tun ti ro ọpọ lagbara loriṣiriṣi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI