Kasnaty ko ẹgbẹrun meji arugbo lọ wẹ lodo igbalode l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 12, 2024

Kasnaty ko ẹgbẹrun meji arugbo lọ wẹ lodo igbalode l'Abẹokuta


Ko din ni ẹgbẹrun meji arugbo ti gbajugbaja sọrọsọrọ nni, Kọlawọle Atanda Adejojo ti ọpọ mọ si Kasnaty Sugar ko lọ wẹ lodo igbalode niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2024.

Pẹlu idunnu ati ayọ ni awọn arugbo ọhun ti ọjọ ori wọn ti le ni ọgọta ọdun daadaa fi gba eto ọhun, ti wọn si ni iru rẹ ko ṣẹlẹ ri.

Ọkan pataki lara awọn to n ṣe iranwọ fun awọn arugbo ni Kasnaty jẹ, to si fẹran lati maa ṣe awọn ohun ti yoo mu inu wọn dun.

Odo igbalode ti a mọ si swimming pool ti ile itura Daktad to wa lagbegbe Quarry Road niluu Abẹokuta ni eto naa ti waye, nibi ti awọn arugbo ti ko din ni ẹgbẹrun meji ti kopa.

Bakan naa la tun ri lara awọn agba oṣere tiata bii Alagba Ọlatunbọsun Ọdunsi ti ọpọ mọ si Baba Amoye, Alagba Kayọde Ọlaṣẹinde ti awọn eeyan tun mọ si Ajirebi, to fi mọ awọn miran.

Yatọ si pe awọn wọnyi gbadun ara wọn, wọn tun gba owo ati ounjẹ loriṣiriṣi.

Nigba to n ṣalaye idi pataki to fi gbe eto naa kalẹ, Kasnaty sọ pe ọjọ alẹ oun loun n tọju silẹ, ati pe ohun to dara pupọ ni lati maa ranti awọn arugbo, ki ọjọ wọn le tubọ pẹ loke eepẹ.

Kasnaty jẹ ko di mimọ pe Ọlọrun lo fi iṣẹ naa ran oun, kii ṣe eeyan, iyẹn lọdun mẹrin sẹyin, to si ni ni oriṣiriṣi eeyan lo ti jẹ anfaani lati ara eto oun.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI