Ipinlẹ Kwara fẹẹ ṣagbekalẹ ina mọnamọna aladani - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 11, 2024

Ipinlẹ Kwara fẹẹ ṣagbekalẹ ina mọnamọna aladani


Ijọba ipinlẹ kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fidi ileri rẹ mulẹ lati ṣagbekalẹ ina mọnamọna aladani fun ipinlẹ naa, lati maa fi pawo wọle.
 
Ina mọnamọna aladani ọhun ti wọn pe ni independent Power Plant (IPP) ni ijọba Kwara sọ pe yoo ṣe iranwọ pupọ ninu idagbasoke eto ọrọ aje wọn.

Kọmiṣanna fọrọ eto ina mọnamọna nipinlẹ Kwara, Onimọ-ẹrọ AbdulAzeez Kola AbdulGaniy lo fidi rẹ mulẹ laipẹ yii niluu Ilọrin.

AbdulGaniy sọ pe iṣẹ ti bẹrẹ lati rii pe ipinlẹ naa bẹrẹ pipese ina mọnamọna tirẹ, ati pe awọn yoo tun maa lo itanṣan oorun, iyẹn Solar lati maa fi ṣe ohun agbara rẹ, eyi to ni fun irọrun araalu ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI