Ileeṣẹ Adron Homes ṣafihan 'Lemon Friday' pẹlu anfaani alaragbayida fun anfaani mẹkunnu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 17, 2024

Ileeṣẹ Adron Homes ṣafihan 'Lemon Friday' pẹlu anfaani alaragbayida fun anfaani mẹkunnu


Ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited ti ṣfihan agbekalẹ ọtun fun igbadun araalu, paapaa awọn onibara wọn, eyi ti wọn pe ni '2024 Lemon Friday Promo'.

Anfaani ọtun alaragbayida ti ko wọpọ leyi jẹ pẹlu bi ileeṣẹ Adron Homes ṣe kede adinku ati sisan owo ọlọjọ-gbọọrọ.

Ọpọ eeyan lo ti n jẹ anfaani yii bọ lati bi ọdun mẹsan sẹyin nipa oriṣiriṣi ipolongo to ti waye, nibi ti awọn eeyan ti n di onile lori pelu ẹbun ọkan-o-jọkan.

Nigba to n sọrọ nibi eto ifilọlẹ too waye ni olu ileeṣẹ Adron Homes nipinlẹ Eko, Arabinrin Adenikẹ Ajọbọ jẹ ko di mimọ pe oriṣiriṣi anfaani lo ti wa nilẹ ti yoo sọ ayalegbe di lanlọọdu lẹẹkan ṣoṣo.

Arabinrin Ajọbọ to jẹ alakoso agba fun ileeṣẹ Adron Homes ni Lemon Friday yii yoo wa lara ọtọ ti ko ṣẹlẹ ri, nitori pe awọn onibara wọn yoo jẹ oriṣiriṣi ẹbun to jọju 

Lara awọn ẹbun naa ni Maalu nla, batiri ina agboorun, ẹrọ amuletutu, firiiji nla, tẹlifiṣan, ifọṣọ ati awọn miran.

Fun alaye lẹkunrẹrẹ, ẹ kan si ileeṣẹ Adron Homes to ba wa ni agbegbe yin, tabi ki ẹ ba wọn sọrọ lawọn oju opo ayelujara wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI